-
Orin Sólómọ́nì 4:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “Wò ó! O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi.
Wò ó! O rẹwà gan-an.
Ojú rẹ rí bíi ti àdàbà, lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú.
Irun rẹ dà bí agbo ewúrẹ́
Tí wọ́n ń rọ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè Gílíádì.+
2 Eyín rẹ dà bí agbo àgùntàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn,
Tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ fún,
Gbogbo wọn bí ìbejì,
Ọmọ ìkankan nínú wọn ò sì sọ nù.
3 Ètè rẹ rí bí òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò,
Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì dùn.
Ẹ̀rẹ̀kẹ́* rẹ rí bí awẹ́ pómégíránétì
Lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú.
-