5 Yí ojú rẹ+ kúrò lọ́dọ̀ mi,
Torí ara mi ò gbà á.
Irun rẹ dà bí agbo ewúrẹ́
Tó ń rọ́ bọ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Gílíádì.+
6 Eyín rẹ dà bí agbo àgùntàn,
Tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ fún,
Gbogbo wọn bí ìbejì,
Ọmọ ìkankan nínú wọn ò sì sọ nù.
7 Àwọn ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ rí bí awẹ́ pómégíránétì
Lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú.