ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 30:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 “Lẹ́yìn náà, kí o mú àwọn lọ́fínńdà tó dáa jù: ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìwọ̀n òjíá dídì àti sínámónì dídùn tó jẹ́ ìdajì rẹ̀, ìyẹn igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n àti igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n ewéko kálámọ́sì dídùn

  • Ẹ́kísódù 30:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Kí o wá fi ṣe òróró àfiyanni mímọ́; kí o ro àwọn èròjà náà pọ̀ dáadáa.*+ Òróró àfiyanni mímọ́ ni yóò jẹ́.

  • Ẹ́sítà 2:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà ló ní ìgbà tí wọ́n máa wọlé sọ́dọ̀ Ọba Ahasuérúsì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ìtọ́jú olóṣù méjìlá tí wọ́n ní kí wọ́n fún àwọn obìnrin, nítorí ohun tí ìtọ́jú aṣaralóge* náà gbà nìyẹn, wọ́n á fi oṣù mẹ́fà lo òróró òjíá,+ wọ́n á sì fi oṣù mẹ́fà lo òróró básámù+ pẹ̀lú oríṣiríṣi òróró ìpara tí wọ́n fi ń ṣe ìtọ́jú aṣaralóge.*

  • Sáàmù 45:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Òjíá àti álóè àti kaṣíà ń já fíkán lára gbogbo aṣọ rẹ;

      Ìró àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín látinú ààfin títóbi lọ́lá tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ń mú inú rẹ dùn.

  • Orin Sólómọ́nì 4:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 “Màá lọ sórí òkè òjíá,

      Màá gba ọ̀nà òkè tùràrí lọ,+

      Títí afẹ́fẹ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́,* tí òjìji kò sì ní sí mọ́.”

  • Orin Sólómọ́nì 5:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dà bí ebè tí wọ́n gbin ewé tó ń ta sánsán sí,+

      Òkìtì ewéko tó ń ta sánsán.

      Ètè rẹ̀ dà bí òdòdó lílì, òjíá olómi+ sì ń kán tótó ní ètè rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́