-
Ẹ́sírà 1:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
1 Ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà, kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà+ sọ lè ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí láti kéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì tún kọ ọ́ sílẹ̀+ pé:
2 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù,+ tó wà ní Júdà.
-
-
Àìsáyà 40:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Gbé ohùn rẹ sókè tagbáratagbára,
Ìwọ obìnrin tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá fún Jerúsálẹ́mù.
Gbé e sókè, má bẹ̀rù.
Kéde fún àwọn ìlú Júdà pé: “Ọlọ́run yín rèé.”+
-