-
Ìṣe 17:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Ọlọ́run tó dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́ Olúwa ọ̀run àti ayé,+ kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì tí a fi ọwọ́ kọ́;+ 25 bẹ́ẹ̀ ni kì í retí pé kí èèyàn ran òun lọ́wọ́ bíi pé ó nílò ohunkóhun,+ nítorí òun fúnra rẹ̀ ló ń fún gbogbo èèyàn ní ìyè àti èémí+ àti ohun gbogbo.
-