ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 36:22, 23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà, kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà+ sọ lè ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí láti kéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì tún kọ ọ́ sílẹ̀+ pé: 23 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù, tó wà ní Júdà.+ Ta ni nínú yín tó jẹ́ èèyàn rẹ̀? Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì lọ síbẹ̀.’”+

  • Ẹ́sírà 6:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 “Ní ọdún kìíní Ọba Kírúsì, Ọba Kírúsì pa àṣẹ kan nípa ilé Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù, ó ní:+ ‘Ẹ tún ilé náà kọ́ kí ẹ lè máa rú àwọn ẹbọ níbẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ sí àyè rẹ̀; kí gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,* kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,+

  • Àìsáyà 45:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 “Mo ti gbé ẹnì kan dìde nínú òdodo,+

      Màá sì mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

      Òun ló máa kọ́ ìlú mi,+

      Tó sì máa dá àwọn ìgbèkùn mi sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ + tàbí láìgba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́