16 Kí ẹ rí i pé ẹ ò jẹ́ kí ọkàn yín fà sí àwọn ọlọ́run míì, kí ẹ wá yà bàrá lọ sìn wọ́n tàbí kí ẹ forí balẹ̀ fún wọn.+ 17 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú sí yín gidigidi, ó sì máa sé ọ̀run pa kí òjò má bàa rọ̀,+ ilẹ̀ ò ní mú èso jáde, ẹ sì máa tètè pa run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà fẹ́ fún yín.+