-
Diutarónómì 28:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Àmọ́ tí o ò bá pa gbogbo àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, gbogbo ègún yìí máa wá sórí rẹ, ó sì máa bá ọ:+
-
-
Diutarónómì 28:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Ojú ọ̀run tó wà lókè orí rẹ máa di bàbà, ilẹ̀ tó sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ máa di irin.+
-
-
1 Àwọn Ọba 8:35, 36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 “Nígbà tí ọ̀run bá sé pa, tí òjò kò sì rọ̀+ torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga, tí wọ́n sì yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé o rẹ̀ wọ́n wálẹ̀,*+ 36 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, ìyẹn àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé wàá tọ́ wọn sí ọ̀nà+ tó yẹ kí wọ́n máa rìn; kí o sì rọ̀jò sórí ilẹ̀ rẹ+ tí o fún àwọn èèyàn rẹ láti jogún.
-
-
2 Kíróníkà 7:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Nígbà tí mo bá sé ọ̀run pa, tí òjò kò sì rọ̀, nígbà tí mo bá pàṣẹ fún àwọn tata láti jẹ ilẹ̀ náà run, tí mo bá sì rán àjàkálẹ̀ àrùn sáàárín àwọn èèyàn mi, 14 tí àwọn èèyàn mi tí à ń fi orúkọ mi pè+ sì rẹ ara wọn sílẹ̀,+ tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n wá ojú mi, tí wọ́n sì kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn,+ nígbà náà, màá gbọ́ láti ọ̀run, màá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, màá sì wo ilẹ̀ wọn sàn.+
-