17 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú sí yín gidigidi, ó sì máa sé ọ̀run pa kí òjò má bàa rọ̀,+ ilẹ̀ ò ní mú èso jáde, ẹ sì máa tètè pa run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà fẹ́ fún yín.+
17Nígbà náà, Èlíjà*+ ará Tíṣíbè, tó ń gbé ní Gílíádì+ sọ fún Áhábù pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí mò ń sìn* ti wà láàyè, kò ní sí òjò tàbí ìrì ní àwọn ọdún tó ń bọ̀, àfi nípa ọ̀rọ̀ mi!”+