7 Ọba ké jáde pé kí wọ́n ránṣẹ́ pe àwọn pidánpidán, àwọn ará Kálídíà àti àwọn awòràwọ̀.+ Ọba sọ fún àwọn amòye Bábílónì pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ka ọ̀rọ̀ yìí, tó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, a máa fi aṣọ aláwọ̀ pọ́pù wọ̀ ọ́, a máa fi ìlẹ̀kẹ̀ wúrà sí i lọ́rùn,+ ó sì máa di igbá kẹta nínú ìjọba.”+