5 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+
Màá mú ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn,
Màá sì kó ọ jọ láti ìwọ̀ oòrùn.+
6 Màá sọ fún àríwá pé, ‘Dá wọn sílẹ̀!’+
Màá sì sọ fún gúúsù pé, ‘Má ṣe dá wọn dúró.
Mú àwọn ọmọkùnrin mi wá láti ọ̀nà jíjìn àti àwọn ọmọbìnrin mi láti àwọn ìkángun ayé,+