-
Diutarónómì 30:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 “Tí gbogbo ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹ sí ọ lára, ìbùkún àti ègún tí mo fi síwájú rẹ,+ tí o sì rántí wọn*+ ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí, 2 tí o wá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, tí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara*+ rẹ fetí sí ohùn rẹ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, 3 nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú+ pa dà wá, ó máa ṣàánú+ rẹ, ó sì máa kó ọ jọ látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí.
-
-
Àìsáyà 66:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Wọ́n máa kó gbogbo àwọn arákùnrin yín jáde látinú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,+ wọ́n á fi wọ́n ṣe ẹ̀bùn fún Jèhófà, lórí ẹṣin, nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, nínú kẹ̀kẹ́ tí wọ́n bo orí rẹ̀, lórí àwọn ìbaaka àti lórí àwọn ràkúnmí tó ń yára kánkán, wọ́n á kó wọn wá sórí òkè mímọ́ mi, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,” ni Jèhófà wí, “bí ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ohun èlò tó mọ́ gbé ẹ̀bùn wọn wá sínú ilé Jèhófà.”
-
-
Ìsíkíẹ́lì 36:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Èmi yóò kó yín látinú àwọn orílẹ̀-èdè, màá pa dà kó yín jọ láti gbogbo ilẹ̀, màá sì mú yín wá sórí ilẹ̀ yín.+
-