-
Mátíù 27:57-60Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
57 Bó ṣe ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ ará Arimatíà dé, Jósẹ́fù lorúkọ rẹ̀, òun náà ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.+ 58 Ọkùnrin yìí lọ bá Pílátù, ó sì ní kó gbé òkú Jésù fún òun.+ Pílátù wá pàṣẹ pé kí wọ́n gbé e fún un.+ 59 Jósẹ́fù gbé òkú náà, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, tó sì mọ́ dì í,+ 60 ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì* rẹ̀ tuntun,+ èyí tó ti gbẹ́ sínú àpáta. Lẹ́yìn tó yí òkúta ńlá sí ẹnu ọ̀nà ibojì* náà, ó kúrò níbẹ̀.
-