ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 5:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Torí pé ilé Ísírẹ́lì ni ọgbà àjàrà Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun;+

      Àwọn èèyàn Júdà sì ni oko* tó fẹ́ràn.

      Ó ń retí ìdájọ́ òdodo,+

      Àmọ́ wò ó! ìrẹ́jẹ ló wà;

      Ó ń retí òdodo,

      Àmọ́ wò ó! igbe ìdààmú ló wà.”+

  • Àìsáyà 59:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Òtítọ́* ti pòórá,+

      Ẹnikẹ́ni tó bá sì yí pa dà kúrò nínú ohun tó burú ni wọ́n ń kó lẹ́rù.

      Jèhófà rí i, inú rẹ̀ ò sì dùn*

      Torí kò sí ìdájọ́ òdodo.+

  • Jeremáyà 5:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Ẹ lọ káàkiri àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù.

      Ẹ wò yí ká, kí ẹ sì kíyè sí i.

      Ẹ wo àwọn ojúde rẹ̀

      Bóyá ẹ lè rí ẹnì kan tó ń ṣe ohun tó tọ́,+

      Ẹni tó fẹ́ máa ṣòótọ́,

      Màá sì dárí jì í.

  • Émọ́sì 6:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ǹjẹ́ àwọn ẹṣin máa ń sáré lórí àpáta,

      Àbí ẹnikẹ́ni lè fi màlúù túlẹ̀ lórí rẹ̀?

      Nítorí ẹ ti sọ ìdájọ́ òdodo di igi onímájèlé,

      Ẹ sì ti sọ èso òdodo di iwọ.*+

  • Hábákúkù 1:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Òfin kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́,

      Kò sì sí ìdájọ́ òdodo rárá.

      Torí àwọn ẹni ibi yí olódodo ká;

      Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń yí ìdájọ́ po.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́