19 Oòrùn ò ní jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ mọ́ ní ọ̀sán,
Ìmọ́lẹ̀ òṣùpá ò sì ní mọ́lẹ̀ fún ọ,
Torí Jèhófà máa di ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,+
Ọlọ́run rẹ sì máa di ẹwà rẹ.+
20 Oòrùn rẹ ò ní wọ̀ mọ́,
Òṣùpá rẹ ò sì ní wọ̀ọ̀kùn,
Torí pé Jèhófà máa di ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,+
Àwọn ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ sì máa dópin.+