21 Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn,+
Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn.+
22 Wọn ò ní kọ́lé fún ẹlòmíì gbé,
Wọn ò sì ní gbìn fún ẹlòmíì jẹ.
Torí pé ọjọ́ àwọn èèyàn mi máa dà bí ọjọ́ igi,+
Àwọn àyànfẹ́ mi sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.