ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 28:19, 20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Jèhófà rẹ Júdà wálẹ̀ nítorí Áhásì ọba Ísírẹ́lì, torí ó ti jẹ́ kí ìwàkiwà gbilẹ̀ ní Júdà, èyí sì mú kí wọ́n máa hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà lọ́nà tó ga.

      20 Níkẹyìn, Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà wá gbéjà kò ó, ó sì kó ìdààmú bá a+ dípò kó fún un lókun.

  • Àìsáyà 7:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Jèhófà máa mú kí ìgbà kan dé bá ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ àti ilé bàbá rẹ, èyí tí kò sí irú rẹ̀ rí láti ọjọ́ tí Éfúrémù ti yapa kúrò lára Júdà,+ torí Ó máa mú ọba Ásíríà wá.+

  • Àìsáyà 7:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa lo abẹ tí wọ́n yá láti agbègbè Odò,* ó máa lo ọba Ásíríà,+ láti fá orí àti irun ẹsẹ̀, ó sì máa fá irùngbọ̀n kúrò pẹ̀lú.

  • Àìsáyà 10:28-32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Ó ti wá sí Áyátì;+

      Ó ti gba Mígírónì kọjá;

      Míkímáṣì+ ló kó ẹrù rẹ̀ sí.

      29 Wọ́n ti kọjá níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà nínú odò;

      Gébà+ ni wọ́n sùn mọ́jú;

      Rámà gbọ̀n rìrì, Gíbíà + ti Sọ́ọ̀lù ti sá lọ.+

      30 Kígbe kí o sì pariwo, ìwọ ọmọbìnrin Gálímù!

      Fiyè sílẹ̀, ìwọ Láíṣà!

      O gbé, ìwọ Ánátótì!+

      31 Mádíménà ti sá lọ.

      Àwọn tó ń gbé Gébímù ti wá ibì kan fara pa mọ́ sí.

      32 Lónìí yìí gan-an, ó máa dúró ní Nóbù.+

      Ó mi ẹ̀ṣẹ́ rẹ̀ sí òkè ọmọbìnrin Síónì,

      Òkè kékeré Jerúsálẹ́mù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́