-
Ìsíkíẹ́lì 8:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Àádọ́rin (70) ọkùnrin lára àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì dúró níwájú wọn, Jasanáyà ọmọ Ṣáfánì+ sì wà lára wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú àwo tùràrí rẹ̀ dání, èéfín tùràrí tó ní òórùn dídùn sì ń gòkè lọ.+ 12 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, kálukú nínú yàrá inú tó kó* àwọn ère rẹ̀ sí? Wọ́n ń sọ pé, ‘Jèhófà ò rí wa. Jèhófà ti fi ilẹ̀ wa sílẹ̀.’”+
-