36 Ìdí nìyẹn tí ọkàn mi á fi kédàárò nítorí Móábù bíi fèrè,+
Ọkàn mi á sì kédàárò nítorí àwọn ọkùnrin Kiri-hérésì bíi fèrè.
Nítorí ọrọ̀ tí ó kó jọ máa ṣègbé.
37 Nítorí gbogbo orí ti pá,+
Gbogbo irùngbọ̀n ni a sì gé mọ́lẹ̀.
Ọgbẹ́ wà ní gbogbo ọwọ́,+
Aṣọ ọ̀fọ̀ sì wà ní ìbàdí wọn!’”+