9 Ó kọ ọ́ sínú àwọn lẹ́tà náà pé: “Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì ní kí Nábótì jókòó sí iwájú gbogbo àwọn èèyàn náà. 10 Kí ẹ ní kí ọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ aláìníláárí jókòó síwájú rẹ̀, kí wọ́n sì ta kò ó+ pé, ‘O ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti sí ọba!’+ Lẹ́yìn náà, kí ẹ mú un jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.”+