1 Sámúẹ́lì 2:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Jèhófà ń pani, ó sì ń dá ẹ̀mí ẹni sí;*Ó múni sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Isà Òkú,* ó sì ń gbéni dìde.+ Jóòbù 33:28 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 28 Ó ti ra ọkàn* mi pa dà kó má bàa lọ sínú kòtò,*+Ẹ̀mí mi sì máa rí ìmọ́lẹ̀.’ Sáàmù 71:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ti mú kí n rí ọ̀pọ̀ wàhálà àti àjálù,+Mú kí n sọ jí lẹ́ẹ̀kan sí i;Gbé mi dìde láti inú kòtò* ilẹ̀ ayé.+
20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ti mú kí n rí ọ̀pọ̀ wàhálà àti àjálù,+Mú kí n sọ jí lẹ́ẹ̀kan sí i;Gbé mi dìde láti inú kòtò* ilẹ̀ ayé.+