Diutarónómì 32:39 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 39 Ẹ rí i báyìí pé èmi, àní èmi ni ẹni náà,+Kò sí ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.+ Mo lè pani, mo sì lè sọni di alààyè.+ Mo lè dá ọgbẹ́+ síni lára, mo sì lè woni sàn,+Kò sí ẹnì kankan tó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.+ Jóòbù 14:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Ká ní o lè fi mí pa mọ́ sínú Isà Òkú* ni,+Kí o fi mí pa mọ́ títí ìbínú rẹ fi máa kọjá,Kí o yan àkókò kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!+ Sáàmù 30:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Jèhófà, o ti gbé mi* sókè látinú Isà Òkú.*+ O mú kí n wà láàyè, o ò sì jẹ́ kí n rì sínú kòtò.*+ Sáàmù 49:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Àmọ́, Ọlọ́run máa rà mí* pa dà kúrò lọ́wọ́ agbára* Isà Òkú,*+Nítorí ó máa dì mí mú. (Sélà) Sáàmù 68:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 Ọlọ́run tòótọ́ ni Ọlọ́run tó ń gbà wá là;+Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì ń gbani lọ́wọ́ ikú.+ Hósíà 13:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Màá rà wọ́n pa dà lọ́wọ́ agbára Isà Òkú;*Màá gbà wọ́n pa dà lọ́wọ́ ikú.+ Ìwọ Ikú, oró rẹ dà?+ Ìwọ Isà Òkú, ìpanirun rẹ dà?+ Síbẹ̀, mi ò ní fojú àánú wò wọ́n.* Jòhánù 11:24 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 24 Màtá sọ fún un pé: “Mo mọ̀ pé ó máa dìde nígbà àjíǹde+ ní ọjọ́ ìkẹyìn.” 1 Kọ́ríńtì 15:55 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 55 “Ikú, ìṣẹ́gun rẹ dà? Ikú, oró rẹ dà?”+
39 Ẹ rí i báyìí pé èmi, àní èmi ni ẹni náà,+Kò sí ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.+ Mo lè pani, mo sì lè sọni di alààyè.+ Mo lè dá ọgbẹ́+ síni lára, mo sì lè woni sàn,+Kò sí ẹnì kankan tó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.+
13 Ká ní o lè fi mí pa mọ́ sínú Isà Òkú* ni,+Kí o fi mí pa mọ́ títí ìbínú rẹ fi máa kọjá,Kí o yan àkókò kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!+
14 Màá rà wọ́n pa dà lọ́wọ́ agbára Isà Òkú;*Màá gbà wọ́n pa dà lọ́wọ́ ikú.+ Ìwọ Ikú, oró rẹ dà?+ Ìwọ Isà Òkú, ìpanirun rẹ dà?+ Síbẹ̀, mi ò ní fojú àánú wò wọ́n.*