ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 3:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Nígbà yẹn, Jòhánù+ Arinibọmi wá, ó ń wàásù+ ní aginjù Jùdíà,

  • Mátíù 3:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Òun gangan ni ẹni tí wòlíì Àìsáyà+ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé: ‘Ẹ ṣètò ọ̀nà Jèhófà!* Ẹ mú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́.’”+

  • Máàkù 1:2-4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Bí a ṣe kọ ọ́ sínú ìwé wòlíì Àìsáyà pé: “(Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi ṣáájú rẹ,* ẹni tó máa ṣètò ọ̀nà rẹ.)+ 3 Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé: ‘Ẹ ṣètò ọ̀nà Jèhófà!* Ẹ mú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́.’”+ 4 Jòhánù Onírìbọmi wà nínú aginjù, ó ń wàásù pé kí àwọn èèyàn ṣèrìbọmi láti fi hàn pé wọ́n ti ronú pìwà dà, kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.+

  • Lúùkù 3:3-6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ó wá lọ sí gbogbo ìgbèríko tó yí Jọ́dánì ká, ó ń wàásù pé kí àwọn èèyàn ṣèrìbọmi láti fi hàn pé wọ́n ti ronú pìwà dà, kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà,+ 4 bí a ṣe kọ ọ́ sínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Àìsáyà pé: “Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé: ‘Ẹ ṣètò ọ̀nà Jèhófà!* Ẹ mú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́.+ 5 Gbogbo àfonífojì gbọ́dọ̀ ga sókè, kí gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké tẹ́jú; àwọn ọ̀nà tó wọ́ gbọ́dọ̀ tọ́, kí àwọn ọ̀nà tó rí gbágungbàgun sì dán; 6 gbogbo ẹran ara* sì máa rí ìgbàlà Ọlọ́run.’”*+

  • Jòhánù 1:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Ó sọ pé: “Èmi ni ohùn ẹni tó ń ké nínú aginjù pé, ‘Ẹ mú ọ̀nà Jèhófà* tọ́,’+ bí wòlíì Àìsáyà ṣe sọ.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́