28 “Bí mo ṣe kíyè sí wọn láti fà wọ́n tu, láti ya wọ́n lulẹ̀, láti fà wọ́n ya, láti pa wọ́n run àti láti ṣe wọ́n léṣe,+ bẹ́ẹ̀ ni màá kíyè sí wọn láti kọ́ wọn bí ilé àti láti gbìn wọ́n,”+ ni Jèhófà wí.
14 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘“Bí mo ṣe pinnu láti mú àjálù wá sórí yín torí àwọn baba ńlá yín múnú bí mi, tí mi ò sì pèrò dà,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,+15 “bẹ́ẹ̀ náà ni mo ṣe pinnu báyìí láti ṣe dáadáa sí Jerúsálẹ́mù àti sí ilé Júdà.+ Ẹ má bẹ̀rù!”’+