2Àwọn yìí ni àwọn èèyàn ìpínlẹ̀,* tí wọ́n pa dà lára àwọn tó wà nígbèkùn,+ àwọn tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kó lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì,+ àmọ́ tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù àti Júdà nígbà tó yá, kálukú pa dà sí ìlú rẹ̀,+
70 Àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn kan lára àwọn èèyàn náà, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú àwọn ìlú wọn, gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì yòókù* sì ń gbé inú àwọn ìlú wọn.+