25Ní ọdún kẹsàn-án ìjọba Sedekáyà, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì dé pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ Ó dó tì í, ó mọ òkìtì yí i ká,+
4 Ní ọdún kẹsàn-án ìjọba Sedekáyà, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, Nebukadinésárì* ọba Bábílónì dé pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. Wọ́n pàgọ́ tì í, wọ́n sì mọ òkìtì yí i ká.+