-
Léfítíkù 25:39-42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
39 “‘Tí arákùnrin rẹ tó ń gbé nítòsí bá di aláìní, tó sì ní láti ta ara rẹ̀ fún ọ,+ má fipá mú un ṣe ẹrú.+ 40 Bí alágbàṣe,+ bí àlejò ni kí o ṣe mú un. Kó máa sìn ọ́ títí di ọdún Júbílì. 41 Kó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ, òun àti àwọn ọmọ* rẹ̀, kó pa dà sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀. Kó pa dà sídìí ohun ìní àwọn baba ńlá rẹ̀.+ 42 Torí ẹrú mi tí mo mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ni wọ́n.+ Kí wọ́n má ta ara wọn bí ẹni ta ẹrú.
-
-
Diutarónómì 15:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Tí wọ́n bá ta ọ̀kan lára àwọn èèyàn rẹ fún ọ, tó jẹ́ Hébérù, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, tó sì ti fi ọdún mẹ́fà sìn ọ́, kí o dá a sílẹ̀ ní ọdún keje.+
-