-
2 Àwọn Ọba 10:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Bó ṣe kúrò níbẹ̀, ó bá Jèhónádábù+ ọmọ Rékábù+ pàdé tó ń bọ̀ wá bá a. Nígbà tó kí i,* ó sọ fún un pé: “Ṣé gbogbo ọkàn rẹ wà* pẹ̀lú mi bí ọkàn mi ṣe wà pẹ̀lú ọkàn rẹ?”
Jèhónádábù fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.”
Jéhù wá sọ pé: “Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.”
Torí náà, ó na ọwọ́ sí i, Jéhù sì fà á gòkè sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.
-