-
Jeremáyà 25:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘“Nítorí pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu, 9 Màá ránṣẹ́ pe gbogbo ìdílé tó wà ní àríwá,”+ ni Jèhófà wí, “màá ránṣẹ́ sí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi,+ màá mú wọn wá láti gbéjà ko ilẹ̀ yìí+ àti àwọn tó ń gbé lórí rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí i ká.+ Màá pa wọ́n run pátápátá, màá sì sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù àti ohun àrísúfèé àti ibi àwókù títí láé.
-