Léfítíkù 26:25 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 25 Èmi yóò mú idà ẹ̀san wá sórí yín torí ẹ da májẹ̀mú+ náà. Tí ẹ bá kóra jọ sínú àwọn ìlú yín, èmi yóò rán àrùn sí àárín yín,+ màá sì mú kí ọwọ́ àwọn ọ̀tá yín tẹ̀ yín.+ Àìsáyà 5:26 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 26 Ó ti gbé àmì sókè* sí orílẹ̀-èdè tó wà lọ́nà jíjìn;+Ó ti súfèé sí wọn pé kí wọ́n wá láti àwọn ìkángun ayé;+Sì wò ó! wọ́n ń yára bọ̀.+ Jeremáyà 1:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Nítorí ‘mò ń pe gbogbo ìdílé àwọn ìjọba àríwá,’ ni Jèhófà wí,+‘Wọ́n á wá, kálukú wọn á sì ṣe ìtẹ́ rẹ̀Sí àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù,+Wọ́n á gbé e ti gbogbo ògiri tó yí i káWọ́n á sì gbé e ti gbogbo ìlú tó wà ní Júdà.+
25 Èmi yóò mú idà ẹ̀san wá sórí yín torí ẹ da májẹ̀mú+ náà. Tí ẹ bá kóra jọ sínú àwọn ìlú yín, èmi yóò rán àrùn sí àárín yín,+ màá sì mú kí ọwọ́ àwọn ọ̀tá yín tẹ̀ yín.+
26 Ó ti gbé àmì sókè* sí orílẹ̀-èdè tó wà lọ́nà jíjìn;+Ó ti súfèé sí wọn pé kí wọ́n wá láti àwọn ìkángun ayé;+Sì wò ó! wọ́n ń yára bọ̀.+
15 Nítorí ‘mò ń pe gbogbo ìdílé àwọn ìjọba àríwá,’ ni Jèhófà wí,+‘Wọ́n á wá, kálukú wọn á sì ṣe ìtẹ́ rẹ̀Sí àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù,+Wọ́n á gbé e ti gbogbo ògiri tó yí i káWọ́n á sì gbé e ti gbogbo ìlú tó wà ní Júdà.+