4 Àwọn ìjòyè sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, ní kí wọ́n pa ọkùnrin yìí,+ torí bó ṣe máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn àwọn ọmọ ogun tó ṣẹ́ kù nínú ìlú yìí àti gbogbo àwọn èèyàn náà nìyẹn, tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún wọn. Nítorí kì í ṣe àlàáfíà àwọn èèyàn yìí ni ọkùnrin yìí ń wá, bí kò ṣe àjálù wọn.”