31 Ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23) ni Jèhóáhásì+ nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútálì+ ọmọ Jeremáyà láti Líbínà.
33 Fáráò Nẹ́kò+ fi í sínú ẹ̀wọ̀n ní Ríbúlà+ nílẹ̀ Hámátì, kó má bàa jọba lórí Jerúsálẹ́mù mọ́, ó wá bu owó ìtanràn lé ilẹ̀ náà, ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà àti tálẹ́ńtì wúrà kan.+