10 Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wò ó, màá ránṣẹ́ pe Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi,+ màá sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ lé orí àwọn òkúta tí mo fi pa mọ́ yìí, á sì na àgọ́ ìtẹ́ rẹ̀ lé wọn lórí.+
19 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Èmi yóò fún Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ yóò kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ, yóò sì kó ọ̀pọ̀ ẹrù rẹ̀, yóò kó o bọ̀ láti ogun; ìyẹn yóò sì jẹ́ èrè fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀.’