-
Àìsáyà 15:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Ìdí nìyẹn tí àwọn ọkùnrin Móábù tó dira ogun fi ń kígbe ṣáá.
Ó* ń gbọ̀n rìrì.
5 Ọkàn mi ń ké jáde torí Móábù.
Àwọn tó sá níbẹ̀ ti sá lọ sí Sóárì+ àti Ẹgilati-ṣẹ́líṣíyà+ lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún.
Wọ́n ń sunkún bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí Lúhítì;
Wọ́n ń ké lójú ọ̀nà Hórónáímù torí àjálù náà.+
6 Torí omi Nímúrímù ti gbẹ táútáú;
Koríko tútù ti gbẹ dà nù,
Kò sí koríko mọ́, kò sì sí ewéko tútù kankan mọ́.
-