22 “Màá dìde sí wọn,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
“Màá pa orúkọ àti àṣẹ́kù run, màá sì pa àtọmọdọ́mọ àti ìran tó ń bọ̀ run kúrò ní Bábílónì,”+ ni Jèhófà wí.
23 “Màá sọ ọ́ di ibùgbé àwọn òòrẹ̀ àti agbègbè tó ní irà, màá sì fi ìgbálẹ̀ ìparun gbá a,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.