-
Àìsáyà 13:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Ará Arébíà kankan ò ní pàgọ́ síbẹ̀,
Olùṣọ́ àgùntàn kankan ò sì ní jẹ́ kí agbo ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.
-
-
Jeremáyà 50:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti wá gbéjà kò ó láti àríwá.+
Ó ti sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ohun àríbẹ̀rù;
Kò sì sí ẹni tó ń gbé inú rẹ̀.
Èèyàn àti ẹranko ti fẹsẹ̀ fẹ;
Wọ́n ti lọ.”
-
-
Jeremáyà 51:29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Ilẹ̀ ayé á mì tìtì, jìnnìjìnnì á sì bá a,
Nítorí pé èrò Jèhófà sí Bábílónì máa ṣẹ
Láti sọ ilẹ̀ Bábílónì di ohun àríbẹ̀rù, tí ẹnì kánkán kò ní gbé ibẹ̀.+
-