ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 17:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Jèhófà lo gbogbo wòlíì rẹ̀ àti gbogbo aríran+ rẹ̀ láti máa kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì àti Júdà pé: “Ẹ kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú yín!+ Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìlànà mi mọ́, bó ṣe wà nínú gbogbo òfin tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, tí mo sì fi rán àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín.”

  • 2 Kíróníkà 36:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ń kìlọ̀ fún wọn léraléra, nítorí pé àánú àwọn èèyàn rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é.

  • Nehemáyà 9:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Wọn ò fetí sílẹ̀,+ wọn ò sì rántí àwọn ohun àgbàyanu tí o ṣe láàárín wọn, àmọ́ wọ́n ya alágídí,* wọ́n sì yan olórí láti kó wọn pa dà sí ipò ẹrú wọn ní Íjíbítì.+ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tó ṣe tán láti dárí jini* ni ọ́, o jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò* àti aláàánú, o kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀* sì pọ̀ gidigidi,+ o ò pa wọ́n tì.+

  • Nehemáyà 9:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Ọ̀pọ̀ ọdún lo fi mú sùúrù fún wọn,+ o sì ń fi ẹ̀mí rẹ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ, àmọ́ wọn ò gbọ́. Níkẹyìn, o fi wọ́n lé àwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wọn ká lọ́wọ́.+

  • Jeremáyà 25:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Jèhófà sì rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì sí yín, léraléra ló ń rán wọn,* ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dẹ etí yín sílẹ̀ láti gbọ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́