-
Jeremáyà 6:12-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ilé wọn máa di ti àwọn ẹlòmíì,
Títí kan àwọn oko wọn àti ìyàwó wọn.+
Torí màá na ọwọ́ mi sí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà,” ni Jèhófà wí.
13 “Látorí ẹni kékeré títí dórí ẹni ńlá, kálukú wọn ń jẹ èrè tí kò tọ́;+
Látorí wòlíì títí dórí àlùfáà, kálukú wọn ń lu jìbìtì.+
Nígbà tí kò sí àlàáfíà.+
15 Ǹjẹ́ ojú tì wọ́n nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe?
Ojú kì í tì wọ́n!
Àní wọn ò tiẹ̀ lójútì rárá!+
Torí náà, wọ́n á ṣubú láàárín àwọn tó ti ṣubú.
Nígbà tí mo bá fìyà jẹ wọ́n, wọ́n á kọsẹ̀,” ni Jèhófà wí.
-
-
Jeremáyà 27:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 “‘“‘Torí náà, ẹ má fetí sí àwọn wòlíì yín, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín, àwọn alálàá yín, àwọn onídán yín àti àwọn oníṣẹ́ oṣó yín, tí wọ́n ń sọ fún yín pé: “Ẹ kò ní sin ọba Bábílónì.”
-
-
Ìsíkíẹ́lì 22:28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Àmọ́ àwọn wòlíì rẹ̀ ti fi ẹfun kun ohun tí wọ́n ṣe. Wọ́n ń rí ìran èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí,” tó sì jẹ́ pé Jèhófà ò sọ̀rọ̀.
-