ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 30:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Wọ́n lọ sí Íjíbítì+ láì fọ̀rọ̀ lọ̀ mí,*+

      Láti wá ààbò lọ sọ́dọ̀ Fáráò,*

      Kí wọ́n sì fi òjìji Íjíbítì ṣe ibi ìsádi wọn!

  • Àìsáyà 31:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Ó mà ṣe fún àwọn tó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Íjíbítì o,+

      Tí wọ́n gbójú lé ẹṣin,+

      Tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ogun, torí pé wọ́n pọ̀,

      Àti àwọn ẹṣin ogun,* torí pé wọ́n lágbára.

      Wọn ò yíjú sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,

      Wọn ò sì wá Jèhófà.

  • Ìdárò 5:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 A ti tẹ́ ọwọ́ wa sí Íjíbítì+ àti Ásíríà,+ ká lè rí oúnjẹ tí ó tó jẹ.

  • Ìsíkíẹ́lì 16:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 O bá àwọn ọmọ Íjíbítì ṣèṣekúṣe,+ àwọn aládùúgbò rẹ oníṣekúṣe,* iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ tó bùáyà sì múnú bí mi.

  • Ìsíkíẹ́lì 17:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Àmọ́ níkẹyìn, ọba náà ṣọ̀tẹ̀ sí i,+ ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí Íjíbítì, kí wọ́n lè fún un ní àwọn ẹṣin+ àti ọmọ ogun púpọ̀.+ Ṣé ó máa ṣàṣeyọrí? Ǹjẹ́ ẹni tó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí á bọ́ lọ́wọ́ ìyà? Ṣé ó lè da májẹ̀mú kó sì mú un jẹ?’+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́