48 Jèhófà máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ dìde sí ọ, o sì máa sìn+ wọ́n tòun ti ebi+ àti òùngbẹ, láìsí aṣọ gidi lọ́rùn rẹ àti láìní ohunkóhun. Ó máa fi àjàgà irin sí ọ lọ́rùn títí ó fi máa pa ọ́ run.
13 Nítorí náà, màá lé yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin tàbí àwọn baba ńlá yín kò mọ̀,+ ibẹ̀ ni ẹ ó ti sin àwọn ọlọ́run míì tọ̀sántòru,+ torí mi ò ní ṣojú rere sí yín.”’