20 Ta ni ọ́, ìwọ èèyàn, tí o fi ń gbó Ọlọ́run lẹ́nu?+ Ṣé ohun tí wọ́n mọ máa ń sọ fún ẹni tó mọ ọ́n pé: “Kí ló dé tí o fi mọ mí báyìí?”+ 21 Kí wá ni? Ṣé amọ̀kòkò ò láṣẹ lórí amọ̀+ láti fi lára ìṣùpọ̀ rẹ̀ mọ ohun èlò kan fún ìlò tó lọ́lá, kí ó sì fi lára rẹ̀ mọ ohun èlò míì fún ìlò tí kò lọ́lá?