15 Àwọn egungun mi ò pa mọ́ fún ọ
Nígbà tí o ṣẹ̀dá mi ní ìkọ̀kọ̀,
Nígbà tí o hun mí ní ìsàlẹ̀ ayé.+
16 Kódà, ojú rẹ rí mi nígbà tí mo ṣì wà nínú ikùn;
Gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ
Ní ti àwọn ọjọ́ tí o ṣẹ̀dá wọn,
Kí ìkankan lára wọn tó wà.