28Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì+ nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+
3 Yàtọ̀ síyẹn, ó mú ẹbọ rú èéfín ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,* ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná,+ ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe.
6 Ó sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná+ ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù;+ ó ń pidán,+ ó ń woṣẹ́, ó ń ṣe oṣó, ó sì yan àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+ Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.