-
Jeremáyà 17:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 “‘“Àmọ́, bí ẹ bá ṣègbọràn sí mi délẹ̀délẹ̀,” ni Jèhófà wí, “tí ẹ kò gbé ẹrù kankan gba àwọn ẹnubodè ìlú yìí wọlé ní ọjọ́ Sábáàtì, tí ẹ sì jẹ́ kí ọjọ́ Sábáàtì máa jẹ́ mímọ́ ní ti pé ẹ kò ṣe iṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà,+ 25 nígbà náà, àwọn ọba àti àwọn ìjòyè, tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì,+ tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹṣin, àwọn àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, máa gba àwọn ẹnubodè ìlú yìí wọlé,+ àwọn èèyàn á sì máa gbé inú ìlú yìí títí láé.
-