ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 28:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Àwọn yìí náà ṣìnà torí wáìnì;

      Ohun mímu wọn tó ní ọtí ń mú kí wọ́n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́,

      Àlùfáà àti wòlíì ti ṣìnà torí ọtí;

      Wáìnì ò jẹ́ kí wọ́n mọ nǹkan tí wọ́n ń ṣe,

      Ọtí wọn sì ń jẹ́ kí wọ́n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́;

      Ìran wọn ń mú kí wọ́n ṣìnà,

      Wọ́n sì ń kọsẹ̀ nínú ìdájọ́.+

  • Jeremáyà 5:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́,+

      Àwọn àlùfáà sì ń fi àṣẹ wọn tẹ àwọn èèyàn lórí ba.

      Àwọn èèyàn mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.+

      Àmọ́, kí lẹ máa ṣe nígbà tí òpin bá dé?”

  • Jeremáyà 6:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 “Látorí ẹni kékeré títí dórí ẹni ńlá, kálukú wọn ń jẹ èrè tí kò tọ́;+

      Látorí wòlíì títí dórí àlùfáà, kálukú wọn ń lu jìbìtì.+

  • Ìsíkíẹ́lì 22:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Àwọn wòlíì rẹ̀ ti gbìmọ̀ pọ̀ ní àárín rẹ̀,+ bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù tó ń fa ẹran ya.+ Wọ́n ń jẹ àwọn èèyàn* run. Wọ́n ń fipá gba ìṣúra àti àwọn ohun iyebíye. Wọ́n ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di opó ní àárín rẹ̀.

  • Sefanáyà 3:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Aláfojúdi ni àwọn wòlíì rẹ̀, oníbékebèke ni wọ́n.+

      Àwọn àlùfáà rẹ̀ ń sọ ohun mímọ́ di ẹlẹ́gbin;+

      Wọ́n ń rú òfin.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́