13 Ṣùgbọ́n ẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan yìí,’ ni Jèhófà wí, ‘àní bí mo tiẹ̀ bá yín sọ̀rọ̀ léraléra,* ẹ kò fetí sílẹ̀.+ Mo sì ń pè yín ṣáá, ṣùgbọ́n ẹ kò dá mi lóhùn.+
10 Àwọn èèyàn búburú yìí, tí kò ṣègbọràn sí ohùn mi,+ àwọn alágídí tó ń ṣe ohun tí ọkàn wọn ń sọ,+ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, tí wọ́n ń sìn wọ́n, tí wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún wọn, àwọn náà yóò dà bí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun mọ́.’