-
2 Kíróníkà 36:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ń kìlọ̀ fún wọn léraléra, nítorí pé àánú àwọn èèyàn rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é. 16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín,+ wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí,+ wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,+ títí ìbínú Jèhófà fi ru sí àwọn èèyàn rẹ̀,+ tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.
-
-
Jeremáyà 25:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 “Láti ọdún kẹtàlá ìjọba Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì, ọba Júdà, títí di òní yìí, ọdún kẹtàlélógún rèé tí Jèhófà ti ń bá mi sọ̀rọ̀, léraléra ni mo sì ń bá yín sọ̀rọ̀,* ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀.+ 4 Jèhófà sì rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì sí yín, léraléra ló ń rán wọn,* ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dẹ etí yín sílẹ̀ láti gbọ́.+
-