-
2 Àwọn Ọba 22:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ọba wá pa àṣẹ yìí fún àlùfáà Hilikáyà, Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì, Ákíbórì ọmọ Mikáyà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáyà ìránṣẹ́ ọba pé: 13 “Ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà nítorí tèmi àti nítorí àwọn èèyàn yìí àti nítorí gbogbo Júdà nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a rí yìí; torí ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná lórí wa kò kéré,+ nítorí àwọn baba ńlá wa kò tẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí láti ṣe gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ fún wa.”
-
-
Jeremáyà 39:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Torí náà, Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ àti Nebuṣásíbánì tó jẹ́ Rábúsárísì* àti Nẹgali-ṣárésà tó jẹ́ Rábúmágì* pẹ̀lú gbogbo èèyàn sàràkí-sàràkí ọba Bábílónì ránṣẹ́ 14 pé kí wọ́n mú Jeremáyà jáde kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ wọ́n sì fà á lé ọwọ́ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì,+ láti mú un wá sí ilé rẹ̀. Torí náà, ó ń gbé ní àárín àwọn èèyàn náà.
-