9 Idà àti ìyàn pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa àwọn tó bá dúró nínú ìlú yìí. Àmọ́ ẹni tó bá jáde, tó sì fi ara rẹ̀ lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó tì yín, á máa wà láàyè, á sì jèrè ẹ̀mí rẹ̀.”’*+
21 “Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Bó ṣe máa rí nìyẹn, nígbà tí mo bá fi oríṣi ìyà mẹ́rin*+ jẹ Jerúsálẹ́mù, ìyẹn idà, ìyàn, àwọn ẹranko burúkú àti àjàkálẹ̀ àrùn,+ kí n lè pa èèyàn àti ẹranko inú rẹ̀ run.+