12 Mo tún bá Ọba Sedekáyà+ ti Júdà sọ̀rọ̀ lọ́nà kan náà pé: “Ẹ mú ọrùn yín wá sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, kí ẹ sì sin òun àti àwọn èèyàn rẹ̀, kí ẹ lè máa wà láàyè.+13 Kí ló dé tí ẹ ó fi jẹ́ kí idà,+ ìyàn+ àti àjàkálẹ̀ àrùn+ pa yín bí Jèhófà ti sọ nípa orílẹ̀-èdè tí kò bá sin ọba Bábílónì?
2 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ẹni tó bá dúró sí ìlú yìí ni idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* yóò pa.+ Àmọ́, ẹni tó bá fi ara rẹ̀ lé* ọwọ́ àwọn ará Kálídíà á máa wà láàyè, á jèrè ẹ̀mí rẹ̀, á sì wà láàyè.’*+
17 Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: “Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Bí o bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, wọ́n á dá ẹ̀mí rẹ sí,* wọn kò ní dáná sun ìlú yìí, wọn kò sì ní pa ìwọ àti agbo ilé rẹ.+